Vol. 15, No. 1, June - December 2023

  1. Home
  2. Call for NED 2023 Papers
  3. Abstracting & Indexing

IPÒ ÀSỌYÉ ÀTI ÀKỌYÉ NÍNÚ ÈTÒ Ẹ̀KỌ́: ÌPÈNÍJÀ FÚN AKẸ́KỌ̀Ọ́ ÀTI OLÙKO

GAJÍBÁDE Mufuliat Ìyábọ̀dé
Department of Yorùbá, Kwara State College of Education, Ilorin
ajibademi17@gmail.com

Àṣamọ̀

Bí a bá wo ipò tí àsọyé àti àkọyé nínú ètò ẹ̀kọ́ wà ní ilẹ̀ wa àti ìhà tí àwùjọ òde òní kọ sí èdè abínibí, ọjọ́ iwájú yóó bani lẹ́rù jọjọ. Kò sí tàbí ṣùgbọ́n pé ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ èdè Yorùbá ni kò lè kọ àkọyé tó gúnrégé tàbí sọ àsọyé tí wọ́n bá fẹ́ jábọ̀ iṣẹ́ àṣetiléwá tàbí àròkọ. Èyi tàbùkù àwọn ènìyàn àwùjọ débi pé o ́dá ìbẹ̀rù bojo sílẹ̀ débi pé àyàfi tí a bá mọ okùnfà ipò ìjákulẹ̀ tí àsọyé àti àkọyé wà láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí a sì wá ojútùú sí i kí ètò ẹ̀kọ́ tó lè pèsè irú àwọn olùdarí tí àwùjọ ń gbòǹgbẹ fún lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́ bí a bá ti kékeré pẹ̀ka ìrókò, bó bá dàgbà tán kò ní lè gba odidi ẹ̀ran lọ́wọ́ ẹni àti pé ìṣín wò ó; ìkòrò wò ó; ohun a bá dìjọ wò gẹ́gẹ́ níí gún. Èyí ló fàá tí iṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí fi ṣe àgbéyẹ̀wò ohun tí èdè, àsọyé àti àkọyé jẹ́, ohun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dì sínú, ipò tí àsọyé àti àkọyé wà nígbà kan rí àti ipò tó wà lóde òní. Iṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí tẹ̀ síwájú láti ṣàlàyé ipa tí títẹpẹlẹ́ àsọyé àti àkọyé lè kó nínú gbogbo ètò ẹ̀kọ́ àti ìdàgbàsókè àwùjọ Yorùbá. Lẹ́yìn èyí, bébà yìí tún tẹ̀ síwájú láti dábàá àwọn ohun àmuṣe àti ojúṣe fún olùkọ́, akẹ́kọ̀ọ́, òbí, ìjọba àti àwùjọ lápapọ̀ ppẹ̀lú èrò láti lè mú ìyàtọ̀ àti ìgbéga bá ipò tí àsọyé àti àkọyé èdè Yorùbá wà nínú ètò ẹ̀kọ́ fún ìbọ̀sípò ìgbé ayé rere fún tolórí tẹlẹ́mù pàápàá àwọn ogo wẹẹrẹ wa láwùjọ Yorùbá.

Share this Article